Ka àwọn ayokà isàlè yil, ki o si dáhún àwọn ibéèrè tí ó tèlé won. Òpò ọdún séyìn, àșà Yorùbá jé àfihàn ìdánimọ̀, ìbùkún àti ìpẹ̀yà fún àwọn tí wọ́n bá tẹ̀sí...

Assessment: JAMB UTME - Yoruba Language - 2025 Subject: Yoruba Language

Question 1 Report

Ka àwọn ayokà isàlè yil, ki o si dáhún àwọn ibéèrè tí ó tèlé won.
Òpò ọdún séyìn, àșà Yorùbá jé àfihàn ìdánimọ̀, ìbùkún àti ìpẹ̀yà fún àwọn tí wọ́n bá tẹ̀síwájú nínú rẹ̀. Àșà àti ìṣe Yorùbá dá lórí ìbáșepọ̀ rere, ìbùkún
àwọn àgbà, ìtẹ́lọ́run ìdílé, àti ìmọ̀ràn tí ó dá lórí ọgbọ́n àwọn baba-nlá wa. Ní gbogbo agbondan Yorùbá, ìyàwó tí a fẹ́ sílẹ, orúkọ tí a fún ọmọ, àwọn
àșà bí a șe ń sajọyọ̀, tàbí bó ṣe yẹ kí a ṣe ìrántí ẹni tó kú, gbogbo wọ́n ní ìtumọ̀ púpọ̀.
Șùgbọ́n, ní àgbáyé òde-òní, pẹ̀lú ìtẹ̀síwájú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àti imọ̀-ẹrọ, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọde àti àwọn ọdọ ti kọ̀ ẹ̀kọ́ àti àșà àwọn baba wọn sílẹ̀. Wón ń fi ẹ̀sùn
kàn an pé àșà jẹ́ ohun ateyinwa, kó sì ní ọ̀rọ̀ tó wúlò mọ́. Kíákíá ni wọ́n fi ń gbàgbọ́ pé àwọn àșà tó jẹ́ ti àwọn orílẹ̀-èdè yòókù dàgbà ju tiwọn lọ.
Ọpọ̀ àwọn obi àti olùkọ́ ló ti wá fìdí re mulẹ̀ bayi pé àìmọ̀ àșà lórí àwọn ọmọde ń fa ìjìyà àti ìtànkálẹ̀ ìbànújẹ nínú awujọ. Bí àpẹẹrẹ, ọmọ tí kò mọ̀
ìtéríba, kò ní lè mọyì àgbà, kó sì ní ifọkàn tán láti fi ọgbọ́n gbà ìpinnu. Nípa bẹ́ẹ̀, àṣà Yorùbá kò yẹ kí ó kú tàbí di aimo, ó yẹ kí a fi ran àwọn ọmọ wa
lọ́wọ́ nínú ẹ̀kọ́, isé, àti ìgbésí-ayé won.

Kí ni ó jẹ́ kí àwọn ọmọde ode-òní bẹ̀rẹ̀ sí í kọ àṣà sílẹ̀?

Answer Details

The passage states the cause plainly: "pẹ̀lú ìtẹ̀síwájú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àti imọ̀-ẹrọ, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọde àti àwọn ọdọ ti kọ̀ ẹ̀kọ́ àti àṣà àwọn baba wọn sílẹ̀" (with the advance of science and technology, many children and youths have abandoned the teaching and culture of their fathers). The advance of science and technology is identified as the driver of this change.

Bad conduct, learning religious doctrine, and an unlucky star are not mentioned anywhere in the passage as reasons for children abandoning their culture; they are unsupported by the text.

For this type of question, trace the cause-and-effect language the passage uses, here "with the advance of...", to find the exact factor the writer blames.

Download The App On Google Playstore

Everything you need to excel in your exams

Green Bridge CBT Mobile App
Personalized AI Learning Chat Assistant
200,000+ Exam Questions Across IGCSE, JAMB, WAEC & NECO
Over 3,900 Lesson Notes
Offline Support - Learn Anytime, Anywhere
Green Bridge Timetable
Literature Summaries & Potential Questions
Track Your Performance & Progress
In-depth Explanations for Comprehensive Learning